1 Kings 8:12-50

12 aNígbà náà ni Solomoni sì wí pé, “Olúwa ti wí pé, òun yóò máa gbé inú òkùnkùn biribiri; 13Nítòótọ́, èmi ti kọ́ ilé kan fún ọ, ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láéláé.”

14Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì dúró síbẹ̀, ọba sì yí ojú rẹ̀, ó sì bùkún fún wọn. 15Nígbà náà ni ó wí pé:

“Ìbùkún ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ìlérí tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé,
16‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti, èmi kò tí ì yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi láti wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ti yan Dafidi láti ṣàkóso àwọn Israẹli ènìyàn mi.’

17“Dafidi baba mi sì ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run Israẹli. 18Ṣùgbọ́n Olúwa sì wí fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi, ó dára láti ní èyí ní ọkàn rẹ. 19Ṣùgbọ́n, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ ilé náà, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ, tí ó tinú ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ jáde; òun ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’

20Olúwa sì ti pa ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe mọ́: Èmi sì ti rọ́pò Dafidi baba mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli báyìí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí, èmi sì kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 21Èmi sì ti pèsè ibìkan níbẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí, èyí tí í ṣe májẹ̀mú Olúwa tí ó ti bá àwọn baba wa dá, nígbà tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá.”

Àdúrà Solomoni fún ìyàsímímọ́

22Solomoni sì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run. 23Ó sì wí pé:

Olúwa Ọlọ́run Israẹli, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ.
24O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí.

25“Ǹjẹ́ báyìí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, ìwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsi ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn. 26Ǹjẹ́ báyìí, Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣe ìlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi wá sí ìmúṣẹ.

27“Ṣùgbọ́n nítòótọ́, Ọlọ́run yóò máa gbé ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò le gbà ọ́. Kí a má sọ pé ilé yìí tí mo kọ́ fún ọ! 28Síbẹ̀ ṣe ìfetísílẹ̀ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ fún àánú, Olúwa Ọlọ́run mi. Gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ lónìí. 29Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí sí ilé yìí ní òru àti ní ọ̀sán, ibí yìí tí ìwọ ti wí pé, orúkọ mi yóò wà níbẹ̀, nítorí ìwọ yóò gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ gbà sí ibí yìí. 30Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Israẹli, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjì.

31“Nígbà tí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì fi wá lé e láti mú un búra, bí ìbúra náà bá sì dé iwájú pẹpẹ rẹ ní ilé yìí, 32nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì ṣe. Kí o sì ṣèdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, dá ènìyàn búburú lẹ́bi, kí o sì mú wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe, dá olóòtítọ́ láre, kí a sì fi ẹsẹ̀ àìlẹ́bi rẹ̀ múlẹ̀.

33“Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹ́gun Israẹli, ènìyàn rẹ, nítorí tí wọ́n ti ṣẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá yípadà sí ọ, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ nínú ilé yìí 34nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ènìyàn rẹ̀ jì í, kí o sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fún àwọn baba wọn.

35“Nígbà tí ọ̀run bá sé mọ́, tí kò sí òjò, nítorí tí àwọn ènìyàn rẹ ti ṣẹ̀ sí ọ, bí wọ́n bá gbàdúrà sí ìhà ibí yìí, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí tí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, 36nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, à ní Israẹli, ènìyàn rẹ. Kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti máa rìn, kí o sì rọ òjò sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún ènìyàn rẹ fún ìní.

37“Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí kòkòrò tí ń jẹ ni run, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá bá dó tì wọ́n nínú àwọn ìlú wọn, irú ìpọ́njú tàbí ààrùnkárùn tó lè wá, 38nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Israẹli wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí, 39nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ. Dáríjì, kí o sì ṣe sí olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ mọ ọkàn rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, 40Nítorí wọn yóò bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọn yóò wà ní ilẹ̀ tí ìwọ fi fún àwọn baba wa.

41“Ní ti àwọn àlejò tí kì í ṣe Israẹli ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ, 42nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí, 43nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́.

44“Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá jáde lọ sí ogun sí àwọn ọ̀tá wọn, níbikíbi tí ìwọ bá rán wọn, nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí Olúwa sí ìhà ìlú tí ìwọ ti yàn àti síhà ilé tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ, 45nígbà náà ni kí o gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró.

46“Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ sí ọ, nítorí kò sí ẹnìkan tí kì í ṣẹ̀, tí ìwọ sì bínú sí wọn, tí ìwọ sì fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ wọn, jíjìnnà tàbí nítòsí; 47bí wọ́n bá ní ìyípadà ọkàn ní ilẹ̀ níbi tí a kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n bá sì ronúpìwàdà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ sí ọ ní ilẹ̀ àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀, àwa ti ṣe ohun tí kò tọ́, àwa ti ṣe búburú’; 48bí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí ìwọ ti fi fún àwọn baba wọn, Ìlú tí ìwọ ti yàn, àti ilé tí èmi kọ́ fún orúkọ rẹ; 49Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn ní ọ̀run, ní ibùgbé rẹ, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró. 50Kí o sì dáríjì àwọn ènìyàn rẹ, tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ; dárí gbogbo ìrékọjá wọn tí wọ́n ṣe sí ọ jì, kí o sì bá àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ wí, kí wọn kí ó lè ṣàánú fún wọn;
Copyright information for YorBMYO